Yoruba Baptist Hymns
OLUGBALA, a tun fe f’ ohun kan
First time here? Explore the hymn tools.
Selected words
Verse 1
OLUGBALA, a tun fe f’ ohun kan,
Yin oruko Re k’ a to tuka lo;
N’ ipari sin, a dide lati yin:
A ‘o si kunle fun ibukun Re.
Verse 2
F’ Alafia fun wa, b’ a tin re ‘le
Je k’ a pari ojo yi pelu Re;
Pa aiya wa mo, si so ete wa.
T’ afi pe oruko Re n’ ile yi.
Verse 3
F’ alafia fun wa l’ oru oni,
So okunkun re d’ imole fun:
Ninu ewu yo awon omo Re.
Okun on ‘mole j’ okanna fun O.
Verse 4
F’ Alafia fun wa ni aiye wa,
Re wa l’ ekun, k’ O si gbe wa n’ ija:
‘Gbat’ O ba si f’ opin s’ idamu wa,
Pe wa, Baba, s’ orun Alafia.
From Yoruba Baptist Hymnshttps://yorubabaptisthymns.com/hymn/olugbala-a-tun-fe-f-ohun-kan/
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.