← Back to the hymnbook
Yoruba Baptist Hymns No. 420

OLUWA, mo gbo pe Iwo

Read. Sing. Share.

Verse 1

OLUWA, mo gbo pe Iwo
Nro ojo ‘bukun kiri;
Itunu fun okan are,
Ro ojo re s’ ori mi.
An’ emi!
Ro ojo re s’ ori mi!

Verse 2

Ma koja Baba Olore,
Bi ese mi tile po;
‘Wo le fi mi sile, sugbon
Jek’ anu Re ba le mi.
An’ emi, etc.

Verse 3

Ma koja mi, Olugbala
Jek’ emi le ro mo O;
Emi nwa oju rere Re,
Pe mi mo awon t’ O npe.
An’ emi, etc.

Verse 4

Ma koja mi, Emi Mimo,
‘Wo le la ‘ju afoju;
Eleri itoye Jesu,
Soro ase na si mi.
An’ emi, etc.

Verse 5

Mo ti sun fonfon nin’ ese,
Mo bi O binu koja;
Aiye ti de okan mi, jo
Tu mi, k’ o dariji mi.
An’ emi, etc.

Verse 6

Ife Olorun ti ki ye;
Eje Krist’ iyebiye;
Ore-ofe alainiwon;
Gbe gbogbo re ga n’nu mi.
An’ emi, etc.

Verse 7

Ma koja mi, dariji mi,
Fa mi roar, Oluwa;
‘Gba O nf’ ibukun f’ elomi,
Ma sai f’ ibukun fun mi.
An’ emi, etc.

Conversation 0 comments

Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.

Share anonymously

No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.

Where are you joining from?

Your city and country appear beside your anonymous comment after review.

Form verification is provided by Cloudflare Turnstile.

Sign in to keep track of replies

Report a lyric correction

Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.

Form verification is provided by Cloudflare Turnstile.Your details are used to respond to this submission.
Support the archive