Yoruba Baptist Hymns
WO! gbogbo ile okunkun
First time here? Explore the hymn tools.
Selected words
Verse 1
WO! gbogbo ile okunkun,
Wo! okan mi, duro je;
Gbogbo ileri ni o nso
T’ ojo ayo t’o l’ ogo;
Ojo Ayo!
K’ owuro re yara de!
Verse 2
Ki India on Afrika,
K’ alaigbede gbogbo ri
Isegun nla t’ o l’ ogo ni,
T’ ori oke Kalfari:
K’ ihinrere
Tan lat’ ilu de ilu.
Verse 3
Ijoba t’ o wa l’ okunkun,
Jesu, tan ‘mole fun won.
Lat’ ila-orun de ‘wo re,
K’ imole le okun lo;
K’ irapada
Ti a gba l’ ofe bori.
Verse 4
Ma tan lo, ‘wo ihinrere,
Ma segun lo, ma duro:
K’ ijoba re aiyeraiye
Ma bi si, k’ o si ma re;
Olugbala
Wa, joba gbogbo aiye.
From Yoruba Baptist Hymnshttps://yorubabaptisthymns.com/hymn/wo-gbogbo-ile-okunkun/
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.