YIN Olorun Oba wa
First time here? Explore the hymn tools.
Verse 1
YIN Olorun Oba wa;
E gbe ohun iyin ga;
Anu Re o wa titi,
L’ ododo dajudaju.
Verse 2
Yin Enit’ oda, orun
Ti o nran l’ojojumo;
Anu Re o wa titi,
L’ododo dajudaju.
Verse 3
Ati osupa l’oru
Ti o ntan ‘mole jeje;
Anu Re o wa titi,
L’ododo dajudaju.
Verse 4
Yin Enit’ o nm’ ojo ro,
T’ O nmu irugbin dagba;
Anu Re o wa titi,
L’ododo dajudaju.
Verse 5
Enit’ O pase fun ‘le
Lati mu eso po si;
Anu Re o wa titi,
L’ododo dajudaju.
Verse 6
Yin fun ikore oko,
O mu ki aka wa kun;
Anu Re o wa titi,
L’ododo dajudaju.
Verse 7
Yin f’onje t’ o ju yi lo,
Eri ‘bukun ailopin;
Anu Re o wa titi,
L’ododo dajudaju.
Verse 8
Ogo f’ Oba olore:
Ki gbogbo eda gberin:
Ogo fun Baba, Omo,
At’ Emi: Metalokan.
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.