1. EKUN ko le gba mi,
Bi mo le f’ekun we ‘ju;
Ko le mu eru mi tan,
Ko le we ese mi nu;
Ekun ko le gba mi.
Jesu sun, o ku fun mi,
O jiya lori igi
Lati so mi di ominira,
On na l’O le gba mi.
2. Ise ko le gba mi;
Ise mi to dara ju,
Ero mi t’o mo julo,
Ko le so ‘kan mi d’otun
Ise ko le gba mi;
3. ‘Duro ko le gba mi,
Enit’o junu ni mi;
L’eti mi l’anu nke pe,
Bi mo ba duro ngo ku;
‘Duro ko le gba mi,
4. Igbagbo le gba mi,
Jeki ngbeke l’Omo Re;
Jeki ngbekele ‘se Re,
Jeki nsa si apa Re,
Igbagbo le gba mi,
(Visited 2,370 times, 3 visits today)