1. EYI, e yipada, ese t’ e o ku,
Nigbat’ Olorun sunmo wa li anu?
Jesu npe nyin, Emi sin wipe k’ e wa,
Angeli si nduro lati mu nyin lo.
2. Asan ni itanje pe t’ a ba duro
Y’ o san okan yin, ewon nyin a yo lo!
Wa t’ iwo t’ ebi re, wa bi o ti ri,
Bi alain’ iranwo lo s’ odo Jesu.
3. Y’ o gba onirobinuje li ofe,
Ese t’ e ko fe gba ‘hinrere na gbo?
B’ ese re l’ o wuwo, ese t’ o ko wa?
O npe o, y’o si se o ni “Ma-wo-‘le.”
(Visited 259 times, 1 visits today)