1. EREDI irokeke yi
Ti enia ti now koja?
‘Jojumo n’ iwojopo na,
Eredi re tin won nse be?
Nwon dahun l’ ohun jeje pe,
“Jesu ti Nasaret’ l’ O nkoja.”
2. Tani Jesu? Ese ti On
Fi nmi gbogbo ilu bayi?
Ajeji Ologbon ni bi,
Ti gbogb’enia nto lehin?
Nwon si tun dahun jeje pe,
“Jesu ti Nasaret’ l’ O nkoja.”
3. Jesu, On na l’ o ti koja
Ona irora wa l’ aiye,
‘Bikibi t’ O ba de, nwon nko
Orisi arun wa ‘do Re:
Afoju yo, lati gbo pe
“Jesu ti Nasaret’ l’ O nkoja.”
4. On sit un de! Nibikibi
Ni awa si nri ‘pase Re;
O nrekoja lojude wa –
O wole lati ba wag be.
Ko ha ye k’ a ayo ke pe,
“Jesu ti Nasaret’ l’ O nkoja.”
5. Ha! e wa enyin t’ orun now,
Gba ‘dariji at’ itunu:
Enyin ti e ti sako lo,
Pada, gba or-ofe Baba;
Enyin t’ a danwo, abo mbe,
“Jesu ti Nasaret’ l’ O nkoja.”
6. Sugbon b’ iwo ko ipe yi,
Ti o sig an ife nla Re:
On yio kehinda si o,
Yio si ko adura re;
“O pe ju” n’ igbe na y’o je: –
“Jesu ti Nasaret’ l’ O nkoja.”