1. ELESE; – mo nfe ‘bukun;
Onde; – mo nfe d’ omnira;
Alare; – mo nfe ‘simi;
“Olorun sanu fun mi.”
2. Ire kan emi ko ni,
Ese sa l’ o yi mi ka,
Eyi nikan l’ ebe mi,
“Olorun sanu fun mi.”
3. Irobinuje okan!
Nko gbodo gb’ oju s’ oke;
Iwo sa mo edun mi;
“Olorun sanu fun mi.”
4. Okan ese mi yi nfe
Sa wa simi l’ aiya Re;
Lat’ oni, mo di Tire;
“Olorun sanu fun mi.”
5. Enikan mbe lor’ ite;
Ninu Re nikansoso
N’ ireti at’ ebe mi:
“Olorun sanu fun mi.”
6. On o gba oran mi ro,
On ni Alagbawi mi;
Nitori Tire nikan,
“Olorun sanu fun mi.”
(Visited 2,510 times, 2 visits today)