YBH 223

TIRE l’ ola Baba

1. TIRE l’ ola Baba,
O wa n’ ikawo Re;
B’ ojum’ ola si mo ba ni,
Nipa ase Re ni.

2. Akoko yi nfo lo,
O ngbe emi wa lo;
Oluwa, mu ‘ranse Re gbon,
Ki nwon le wa fun O.

3. Akoko t’ o nlo yi,
L’ aiyeraiye ro mo;
Fi agbara Re, Oluwa,
Ji agba at’ ewe.

4. Ohun kan l’ a le du,
T’ a ba ma le ‘pa re;
Pe k’ igba ‘bewo wa ma lo,
Latitun pada wa mo.

5. Jek’ a sa to Jesu,
K’ a si sure tete,
K’ emi wa ma ba ku, k’ o ri
S’ okun biribiri.

(Visited 426 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you