YBH 222

BI mo ti ri – laisawawi

1. BI mo ti ri – laisawawi,
Sugbon nitori eje Re,
B’O si ti pe mi pe ki nwa –
Olugbala, mo de.

2. Bi mo ti ri – laiduro pe,
Mo fe k’okan mi mo toto,
Sodo Re t’o le we mi mo.
Olugbala, mo de.

3. Bi mo ti ri -b’o tile je
Ija l’ode, ija ninu;
Eru l’ode, eru ninu –
Olugbala, mo de.

4. Bi mo ti ri -osi, are,
Mo si nwa imularada;
Iwo l’o le s’awotan mi –
Olugbala, mo de.

5. Bi mo ti ri -‘wo o gba mi,
‘wo o gba mi t’owo t’ese
‘Tori mo gba ‘leri Re gbo –
Olugbala, mo de.

6. Bi mo ti ri – ife Tire
L’ o sele mi patapata;
Mo di Tire, Tire nikan –
Olugbala, mo de.

(Visited 3,469 times, 3 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you