1. WA, Jesu fi ara han;
Wa, je k’okan wa mo O:
Wa, mu gbogb’ okan gbona,
Wa, bukun wa k’a to lo.
2. Wa, f’ aiya wa n’ isimi,
Wa, k’ a d’ alabukunfun;
Wa, s’ oro alafia,
Wa, busi igbagbo wa.
3. Wa, le ‘siyemeji lo,
Wa, ko wa b’ a ti bebe;
Wa, fun okan wa n’ife,
Wa, fa okan wa s’oke.
4. Wa, so f’ okan wa k’ o yo,
Wa, wipe, “‘Wo ni mo yan”;
Wa, p’ awon agbo Re mo,
Wa, sure f’ agutan Re.
(Visited 807 times, 1 visits today)