1. TIRE lailai l’ awa se,
Baba Olorun ife;
Je k’ a je Tire titi,
L’ aiye yi, ati lailai.
2. Tire lailai l’ awa se,
Ma toju wa l’ aiye yi:
‘Wo iye, Ona, Oto,
To wa si ilu orun.
3. Tire lailai: – Abukun
L’ awon t’ O se ‘simi won!
Olugbala, Ore wa,
Gba ‘ja wa ja de opin.
4. Tire lailai:- Jesu pa
Awon agutan Re mo;
Labe iso rere Re,
Ni k’O pa gbogbo wa mo.
5. Tire lailai: Aini wa
Ni o je aniyan Re;
O ti f’ese wa ji wa,
To wa si ibugbe Re.
(Visited 1,070 times, 1 visits today)