YBH 233

DIDE okan mi, nde

1. DIDE okan mi, nde
Gbon eru ebi nu;
Ebo eje t’a ru
Nitori mi yoju:
Jesu duro niwaju ‘te,
A k’oruko mi s’owo Re.

2. Apa wa l’ara Re,
T’O gba ni kalfari,
Nwon nf’itara s’oro,
Nwon si mbebe fun mi;
“Jowo, dariji,” ni nwon nke
“Mase je k’elese ni ku.”

3. Baba gbo ohun Re,
Eni ororo ni;
Ko le m’eti kuro
N’nu ebe Omo Re;
Emi Re da eje ohun,
O wip’om’Olorun ni mi.

4. Mo b’Olorun la’ja,
Mo gbo ‘dariji Re,
O gba mi fun omo,
Iberu ko si mo;
Mo f’ igboya omo sunmo,
Mo si nke pe. “Abba Baba.”

(Visited 560 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you