1. JESU ti mo gbeke mi le,
At’ ireti mi lo s’ orun:
Mo r’ ipa Re, ngo si tele
Ona Re titi ngo fi ri.
2. Ona ti awon mimo to,
T’ o kuro lona iyapa,
Ona-ero mimo t’ Oba,
Ngo lo s’ on’ alafia Re.
3. Ona ti mo ti nwa l’ eyi,
Ti mo ns’ ofo pe nko ri i;
Ibanuje, mi sa tip e,
Nitori nko le y’ ese da.
4. Bi mo ti mba ipa Re ja,
Beni mo si nsubu si i;
Ko pe ti mo gbo Jesu pe,
“Okan wa ‘hin, Emi l’ Ona.”
5. Mo f’ ayo wa Od’ – agutan;
‘Wo o gba mi bi mo ti ri,
Mo f’ ara ese mi fun O,
Ife nikan ni ngo si gba.
(Visited 516 times, 1 visits today)