1. APATA aiyeraiye,
Se ibi isadi mi!
Je ki omi on eje
T’ o san lati iha Re
Se iwosan f’ ese mi,
K’ o si so mi di mimo.
2. K’ ise ise owo mi,
L’ o le mu ofin Re se;
B’ itara mi ko l’ are,
T’ omije mi nsan titi,
Nwon ko to fun etutu,
‘Wo nikan l’ O le gbala.
3. Ko s’ ohun ti mo mu wa,
Mo ro mo agbelebu;
Mo wa, k’od’ as obo mi,
Mo now O fun iranwo;
Mo wa sib’ orison ni,
We mi, Olugbala mi.
4. ‘Gbat emi mi ba n lo,
T’ iku ba p’ oju mi de,
Ti mba lo s’ aiye aimo,
Ti nri O n’ ite ‘dajo;
Apata aiyeraye,
Se ibi isabi mi.
(Visited 10,623 times, 11 visits today)