YBH 236

NIGBA itiju k obo mi

1. NIGBA itiju k obo mi,
Mo f’ eru sa b’ agbelebu;
Pelu eru ebi lori,
Ife fa mi, mo bo ‘waju,
Mo r’ anu at’ alafia,
Nipa eje Jesu Kikun.

2. Ese mi lo, eru mi tan,
Nko si sa fun oju Re, mo;
O joko lor’ ite anu,
O ni ki nf’ igboiya wa On;
Mo ri eje etutu ni,
A fi won or’ ite yika.

3. Alufa mi yo siwaju,
Baba gbo t’ Alagbawi mi;
Eje owon ni nke f’ anu
Niwaju Re t’ osan, t’ oru.
Nigbakugba ni eje na
Ma mbe niwaju Olorun.

4. Mo le simi laisi ‘beru;
Nip’ eyi mo sunm’ Olorun;
Nip’ eyi mo segun ese;
Nitor’ O so mi di mimo.
Gba mo ba de ite loke,
Ngo yin eje etutu na.

(Visited 337 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you