1. JESU oluf’ okan mi,
Je ki nsala s’ aiya Re;
Sa t’ irumi sunmo mi,
Sa ti iji fe s’ oke;
Pa mi mo, Olugbala,
Tit’ iji aiye y’o pin,
To mi lo s’ ebute Re,
Nikehin gb’ okan mi la.
2. Abo mi, emi ko ni,
Iwo l’ okan mi ro mo;
Ma f’ emi nikan sile,
Gba mi, si tu mi ninu.
Iwo ni mo gbekele,
Iwo n’iranlowo mi,
Ma sai f’iye apa Re
D’abo b’ori aibo mi.
3. Krist’,’wo nikan ni mo fe,
N’nu Re, mo r’ohun gbogbo;
Gb’emi t’o subu dide,
W’alaisan, to afoju;
Ododo l’oruko Re,
Alaisododo l’emi,
Mo kun fun ese pupo,
Iwo kun fun ododo.
4. ‘Wo l’opo ore-ofe
Lati fib o ese mi:
Je ki omi iwosan
We inu okan mi mo;
Iwo l’orisun iye,
Je ki mbu n’nu Re l’ofe,
Ru jade n’nu okan mi,
Si iye ainipekun.
(Visited 2,294 times, 1 visits today)