1. JESU, ise Re l’o
Fi ayo s’okan mi,
Nwon ni, o ti pari,
Ki eru mi ko tan:
Odo tani emi ‘ba lo,
Lehin Iwo t’O s’etutu?
2. Jesu,ogbe Re l’o
Le m’okan mi jina;
N’nu ‘ya Re ni mo ri
Iwosan f’ese mi:
Odo tani emi ‘ba lo,
Lehin Iwo t’O s’etutu?
3. Agbelebu Tire
L’o gbe eru ese,
T’enikan ko le gbe,
Lehin Om’Olorun:
Odo tani emi ‘ba lo,
Lehin Iwo t’O s’etutu?
4. Ki se iku t’emi
L’o san irapada;
Egbarun bi t’emi
Ko to, o kere ju;
Odo tani emi ‘ba lo,
Lehin Iwo t’O s’etutu?
(Visited 1,612 times, 1 visits today)