1. OLUWA l’ atilehin mi,
Kini ‘ba te mi ri?
Eniti O da aiye ro,
T’ O ta sanma l’ aso.
2. Ki nku, nigbati Jesu ji
Kuro larin iku?
Okan mi ti gba ‘dariji
Lowo Olori mi.
3. Emi, at’ ohun ti mo ni,
Y’o je Tire lailai;
Ohun ti ko to s’ ipo mi,
L’ ayo mo fi fun O.
4. B’ ohun kan si mbe ti ipo
Ko bere l’ owo mi,
Ife nla si Olorun to
Mu mi fi kun pelu.
(Visited 725 times, 1 visits today)