1. KI nko ohun gbogbo sile
Fun O, Oluwa mi
O to be, niwon b’ O ti se
Rekoja ‘yi fun mi.
2. Je k’ o lo, iriju Re kan,
O ju gbogbo re lo;
Y’o dipo adamu ore,
Oruko at’ oro.
3. Egbarun aiye at’ emi,
Bi nwon ti kere to!
L’ egbe Re, Onibu ore,
Iwo ‘Mole orun.
4. Mba le ri ojurere kan
Lati odo Re wa;
Mo le p’ adamu ini mi
Fun ayo ere mi.
(Visited 476 times, 1 visits today)