1. ENI ba gbekel’ Olorun,
L’ abo l’ orun at’ aiye:
Eni ba f’ ife wo Jesu,
Ko s’ eru ti damu re.
2. Lara Re nikan, Oluwa,
Ni mo r’ adun itunu;
Asa f’ ota at’ ogun mi,
Igbala mi t’ o daju.
3. Nimu ijakadi aiye,,
Emi o duro sinsin;
Idanwo y’ o so ‘pa re nu,
Nitori ‘Wo o so mi.
4. Oluwa, se ‘ri ‘bukun Re
S’ ara ati okan mi:
Je t’ emi, si se mi n’tire,
Nitori iku Jesu.
(Visited 1,935 times, 2 visits today)