1. PIPE n’ ise ‘gbala,
Lekan o pari lai;
Pipe ni ododo,
Ti o bo elese:
Ife t’ o bukun wa l’ aiye,
O nsan l’ ofe nisisiyi.
2. Irubo to koja,
A ke ‘kele meji;
Ite anu kun fun
Eje ohun ‘rubo:
Ese t’ a f’ eru wa l’ ode,
Eje mimo nwipe k’ a wa.
3. Alufa giga wa
Lori ite anu;
Eje t’ o mu w ape
O wa li owo Re:
E jek’ a f’ igboiya sunmo,
Eje ni le ifoiya lo.
(Visited 684 times, 1 visits today)