YBH 243

WO Ore okan ti nkanu

1. WO Ore okan ti nkanu!
T’ O feran nwon titi d’ opin
Eyi n’ ireti mi ro mo,
Pe’ “‘Wo o be fun mi.”

2. Gbat’ are de n’ ire-ije,
T’ ib’ isimi mi han lokan,
Ti nko si gba anu Re gbo,
‘Gbana k’ O be fun mi.

3. ‘Gba mo ba se, ti mo sonu
Kuro li ona ogbon Re,
Ti nko si ri olutona,
Sibe k’ O be fun mi.

4. ‘Gb’ ese mi gbo Esu l’ aiya,
T’ o nfe ja ‘wo mi l’ ara Re;
Jo! F’ owo anu Re gba mi,
K’ O si bebe fun mi.

5. ‘Gbat’ iku mi nsunmo ‘tosi,
Ti eru m’ oju mi s’ okun,
Jo! Han si baibai oju mi,
Nipo ebe fun mi.

(Visited 374 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you