1. MO k’ ese mi le Jesu,
Od’ agutan mimo;
O ru gbogbo eru mi,
O so mi d’ominira;
Mo rue bi mi to wa
K’Owe eri minu.
K’eje Re iyebiye
Le so mi di funfun.
2. Mo k’aini mi le Jesu,
Tire l’ohun gbogbo;
O w’arun mi gbogbo san
O r’emi mi pada.
Mo ko ibanuje mi,
Eru at’aniyan,
Le Jesu, O si gba mi,
O si gba irora mi.
3. Mo gb’okan mi le jesu,
Okan are mi yi;
Ow’otun Re gba mi mu,
Mo simi l’aiya Re;
Mo fe oruko Jesu,
Emmanuel’, Kristi,
Bi orun didun yika,
Li oruko Re je.
4. Mo fe ki nri bi Jesu
T’ okan Re kun fun ‘fe;
Mo fe ki nri bi Jesu.
Omo Mimo Baba;
Mo fe ki mba Jesu gbe,
Larin egbe mimo,
Ki nkorin iyin titi,
Orin t’ angeli nko.
(Visited 698 times, 1 visits today)