1. NIPA ife Olugbala,
Ki y’o si nkan;
Oju rere Re ki pada.
Ki y’o si nkan.
Owon l’eje t’o wo wa san,
Pipe l’edidi or’-ofe,
Agbara l’owo t’o gba ni,
Ko le si nkan.
2. Bi a wa ninu iponju,
Ki y’o si nkan:
Igbala kikun ni ti wa.
Ki y’o si nkan.
Igbekele Olorun dun,
Gbigbe inu Kristi l’ere,
Emi si nso wa di mimo
Ko le si nkan.
3. Ojo ola yio dara,
Ki y’o si nkan.
‘Gbagbo le korin n’iponju
Ki y’o si nkan
A gbekele ‘fe Baba wa,
Jesu fun wa l’ohun gbogbo.
Ni yiye tabi ni kiku
Ko le si nkan.
(Visited 12,912 times, 22 visits today)