1. OLUWA, Baba orun,
B’ oju woo mo-‘do Re
Ti nro t’ igbe aiye re,
Ati ipo re si O.
2. Mo n’ igbgbo si Jesu,
Si agbara iku Re,
S’ ajinde Re, apere
Iye lehin iku mi.
3. Emi Re l’ o s’ ise yi,
L’ O mu mi mo ebi mi,
L’ O toka ‘gbala si mi,
L’ O mu mi gba Kristi gbo.
4. Sugbon sibe okan mi,
Nd’igba se kilakilo,
Nitor’ese to mo nda,
Alailera sa l’emi.
5. Fun mi ni idaloju
Isimi okan toto,
T’awon ‘mo-ehin Re gbo,
Ti aiya won si bale.
6. Wi f’okan mi, Oluwa,
(Iwo nikan l’O le wi,)
Pe a ti k’oruko re
Sinu ‘we iye l’oke.
7. ‘Gbana mo le n’igboya
Lati wi bi paulu pe,
“Ko s’ohun l’aiye, l’orun
T’o le ya t’emi Tire.”
Support Yoruba Baptist Hymns
Every week, thousands of believers use YorubaBaptistHymns.com to access Yoruba Baptist hymns for worship and ministry.
In the last 6 months alone, people searching for Yoruba Baptist hymns found this platform over 297,000 times on Google, with more than 48,000 visitors every month.
If this platform has blessed you or your church, consider helping sustain this hymn archive so it remains available for worshippers around the world.