YBH 251

APATA aiyeraiye

1. APATA aiyeraiye,
Enit’ o mbe lailai,
Nigbakugba t’ iji nja,
‘Bugbe wa y’o gbe je:
Saju dida aiye yi,
Iwo mbe; bakanna
Tit’ aiye ainipekun,
Aiyeraiye ni ‘Wo.

2. Oj’ odun wa ri b’ oji
T’ o han l’ ori oke:
Bi koriko ipado,
T’ o ru ti o si ku,
Bi ala; tabi b’ itan
T’ enikan nyara pa:
Ogo ti ko ni si mo,
Ohun t’ o gbo tan ni.

3. ‘Wo Eniti Ki togbe,
‘Mole Enit’ itan;
Ko wa bi a o ti ka
Ojo wa, k’ o to tan;
Je k’ anu Re ba le wa,
K’ ore Re po fun wa;
Si je k’ Eni Mimo Re,
Mole si okan wa.

4. Jesu, f’ ewa at’ ore,
De ‘gbagbo wa l’ ade;
Tit’ ao fi ri O gbangba,
Ninu ‘mole lailai;
Ayo t’ enu ko le so,
Orisun akunya,
Alafia ailopin,
Okun ailebute.

(Visited 1,381 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you