1. GBA mo le ka oye mi re,
Ni ibugbe l’oke;
Mo dagbere f’eru gbogbo,
Mo n’omije mi nu.
2. B’aiye kojuja s’okan mi,
T’a nso oko si I,
‘Gbana mo le rin Satani,
Mo le je ‘ju k’aiye.
3. K’aniyan de b’ikun omi,
K’iji ‘banuje ja;
Ki nsa de ‘le Alafia,
Olorun, gbogbo mi.
4. Nibe l’okan mi y’o luwe,
N’nu okun ‘b’isimi;
Ko si wahala to le de,
S’ibale aiya mi.
(Visited 1,036 times, 1 visits today)