YBH 256

IGBAGBO mi duro l’ori

1. IGBAGBO mi duro l’ori,
Eje at’ododo Jesu;
Nko je gbekele ohun kan,
Lehin oruko nla Jesu;
Mo duro le Krist’Apata,
Ile miran, iyanrin ni.

2. B’ire-ije mi tile gun,
Or’-ofe Re ko yipada:
B’o ti wu k’iji na le to,
Idakoro mi ko ni ye:
Mo duro le Krist’Apata,
Ile miran, iyanrin ni.

3. Majemu ati eje Re,
L’em’o ro mo b’ikunmi de:
Gbati ohun aiye bo tan,
O je ireti nla fun mi;
Mo duro le Krist’Apata,
Ile miran, iyanrin ni.

4. Gbat’ipe kehin ba si dun,
A! mba le wa l’odo Jesu,
Ki now ododo Re nikan.
Ki nduro niwaju ite.
Mo duro le Krist’Apata,
Ile miran, iyanrin ni.

(Visited 16,656 times, 11 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you