1. OLORUN mi bojuwo mi
F’ iyanu ‘fe nla Re han mi;
Ma je ki ngbere fun ‘ra mi,
Tori ‘Wo si ngbero fun mi;
Baba mi to mi l’aiye yi
Je k’ igbala Re to fun mi.
2. Ma je ki mbu le O lowo,
‘Tori ‘Wo li onipin mi,
S’ eyi t’ Iwo ti pinnu re,
Iba je’ ponju tab’ ogo.
3. Oluwa tal’ o r’ idi Re,
Iwo Olorun Ologo?
Iwo l’ egbegberun ona
Nibiti nko ni ‘kansoso.
4. B’ orun ti ga ju aiye lo,
Bel’ ero Re ga ju t’ emi,
Ma dari mi k’ emi le lo
S’ ipa ona ododo Re
(Visited 6,292 times, 11 visits today)