1. NIGBA nwon kehin si Sion,
A! opo n’ iye won;
Mo seb’ Olugbala wipe,
‘Wo fe ko mi pelu?
2. T’ emi t’ okan b’ iru eyi
A fi b’ O di mi mu;
Nko le se kin ma fa sehin
K’ emi si dabi won.
3. Mo mo, Iwo l’ o l’ agbara
Lati gba otosi;
Odo tani emi o lo,
Bi mo k’ ehni si O?
4. O da mi loju papa pe
Iwo ni Kristi na!
Enit’ o ni emi iye
Nipa ti eje Re
5. Ohun Re f’ simi fun mi,
O si l’ eru mi lo;
Ife Re l’ o le mu mi yo
O si to f’ okan mi.
6. Bi ‘bere yi ti dun mi to,
“Pe emi o lo bi?”
Oluwa ni ‘gbekele Re,
Mo dahan pe, “Beko.”
Support Yoruba Baptist Hymns
Every week, thousands of believers use YorubaBaptistHymns.com to access Yoruba Baptist hymns for worship and ministry.
In the last 6 months alone, people searching for Yoruba Baptist hymns found this platform over 297,000 times on Google, with more than 48,000 visitors every month.
If this platform has blessed you or your church, consider helping sustain this hymn archive so it remains available for worshippers around the world.