YBH 259

ALAFIA, li aiye ese yi

1. ALAFIA, li aiye ese yi,
Eje Jesu nwipe, “Alafia!”

2. Alafia, ninu opo lala?
Lati se ife Jesu ni ‘simi.

3. Alafia, n’nu igbi ‘banuje?
L’ aiya Jesu n’ idakeroro wa.

4. Alafia, gb’ ara wa wa l’ ajo?
N’ ipamo Jesu, iberu ko si.

5. Alafia, b’ a ko tile m’ ola?
Sugbo a mo pe Jesu wa lailai.

6. Alafia, nigb’ akoko iku?
Olugbala wa ti segun iku.

7. O to: ‘jakadi aiye fere pin,
Jesu y’ o pe wa s’ orun alafia.

(Visited 2,275 times, 2 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you