YBH 263

NGO fe O, Olorun Baba

1. NGO fe O, Olorun Baba,
Olugbala, Oba mi;
Ngo fe O, ‘tori laisi Re
Aiye j’ ohun kikoro.

2. Ngo fe O, gbogbo ibukun
Nsan lat’ ife Re si mi;
Ngo fe O, enit’ o fe O
Ko le wa nikan lailai.

3. Ngo fe O, ma bojuto mi,
Ma fi oju Re to mi;
Ngo fe O, okan mi yio ku
Bi ko r’ onje ife Re.

4. Mo ti j’ eje pe ngo fe O,
Mo gb’ okan le ife Re;
Bi mba fe O, nki o gbagbe
Eje Olugbala mi.

(Visited 1,219 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you