1. MO fe O, Olorun, sugbon
Ki se fun ere kan,
Ki se nitori’ eniti
Ko ba fe O yio ku,
Mo fe O, Olorun, sibe
Ngo ma fe O titi;
‘Torip’ Olorun mi ni O,
Ti O tete fe mi.
2. O re ‘ra ‘le nitori mi,
Titi d’ opin ise;
O gb’ agbelebu at’ egan,
At’ itiju fun mi;
O je ‘rora pupo fun mi,
O kan ogun eje,
Ani, ko si ko lati ku
Fun emi ota Re.
3. Ko ha to, Olugbala mi,
Ki nfe O de opin:
Ki se lati jere orun,
Tab’ ifoya ‘parun.
Ki se nitori ohun kan,
Tabi fun ere kan:
Sugbon l’ ofe gege bi O
Ti fe mi, Oluwa.
(Visited 624 times, 1 visits today)