1. Ife orun, o ti dun to!
Gbawo ni ngo ri t’okan mi,
Y’o kun fun kiki re?
Okan mi npongbe lati mo
Riri ife irapada;
Ife Kristi si mi.
2. Ife Re n’ipa ju iku;
Oro Re awa awamaridi!
Awon Angeli papa
Wa ijinle ife yi ti.
Nwon ko le mo iyanu na
Giga at’ibu re.
3. Olorun nikan l’O le mo,
Iba je tan ka’le loni;
L’okan okuta yi!
Ife nikan ni mo ntoro,
Ko je ipin mi Oluwa:
K’ebun yi je t’emi.
4. Emi iba le joko lai,
Bi Maria, l’ese Jesu;
K’eyi je ayo mi;
K’oj’aniyan at’ife mi,
K’o si j’orun fun mi l’aiye,
Lati ma gb’ohun Re.
(Visited 349 times, 1 visits today)