1. NGO feran Re, Wo odi mi;
Ngo feran Re, ‘Wo ayo mi;
Ngo feran Re, patapata;
Ngo feran Re, tor’ ise Re,
Ngo feran Re, tit’ okan mi,
Y’o fi kun fun ife rere.
2. ‘Wo Orun mi, gba ope mi,
Fun ‘mole Re t’o fi fun mi,
Gba ope mi, ‘Wo l’ o gba mi
Lowo awon ti ns’ ota mi.
Gba ope mi fun ohun Re
T’ o mu mi yo l’ opolopo.
3. N’nu ire-ije l’ aiye,
Ma se alabojuto mi,
Fi agbara fun ese mi,
Ki nle t’ ese m’ ona rere;
Ki mba le f’ ipa mi gbogbo
F’ oruko Re t’ o l’ ogo han.
4. Ngo feran Re, ‘Wo ade mi,
Ngo feran Re, Oluwa mi,
Ngo feran Re, nigbagbogbo,
L’ ojo ibi, l’ ojo ire,
Gbati ojo iku ba de,
Ngo feran Re titi lailai.
(Visited 1,164 times, 1 visits today)