1. B’ORUKO Jesu ti dun to
L’ eti olugbagbo!
O tan ‘banuje on ogbe,
O le eru re lo.
2. O mu ogbe emi re tan,
O mu aiya bale;
Manna ni fun okan ebi,
Isimi f’ alare.
3. Ailera l’ agbara ‘nu mi,
Tutu si l’ ero mi,
‘Gba mo ba ri O b’ O ti ri,
Ngo yin O b’ o ti ye;
4. Tit’ igbana ni ohun mi
Y’ o ma rohin ‘fe Re;
Nigba iku k’ oruko Re,
F’ itura f’ okan mi.
(Visited 1,975 times, 2 visits today)