YBH 298

ODODO Re nikan laise t’ emi

1. ODODO Re nikan laise t’ emi,
L’ o le se isimi fun okan mi;
Ife Re l’ o le mu k’ ifoiya lo,
L’ o le da iji okan mi l’ ekun.

2. Agbelebu wipe ife ni O,
Mo si ka ife lor’ iboji Re;
Gbogbo ife miran ni y’o parun,
Eyi y’o mu mi ja okun aiye.

3. O bukun, O si gba okan mi la,
Nisisiyi ati aiyeraiye,
‘Gbati ko si ‘ranwo, O gbe mi ro,
O gbe mi le ‘ke igbi iponju.

4. F’ ara han mi ni wakati gbogbo,
At’ opo ogo Re, Oluwa mi,
F’ ara han n’nu anu at’ ipa Re,
F’ ife ati otito Re han mi.

(Visited 413 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you