1. EWE ti Oba orun,
Korin didun b’ e ti nlo;
Korin ‘yin t’ Olugbala,
Ise Enit’ o l’ ogo.
2. E nlo sodo Olorun,
L’ ona t’ awon baba nrin,
Nwon si nyo nisisiyi,
Ayo won l’ enyin o ri.
3. Korin agbo kekere,
E o simi n’ ite Re;
Ib’ a pese ‘joko nyin,
Ibe si n’ ijoba nyin.
4. Woke, omo imole,
Ilu Sion wa lokan:
Ibe n’ ile wa titi,
Ibe l’ a o r’ Oluwa.
5. Ma sa, e duro l’ ayo,
Ni eti ile tin yin,
Kristi Omo Baba nwi
Pe, laifoya k’ a ma lo.
6. Jesu, a nlo l’ase Re,
A ko ‘hun gbogbo sile,
Iwo ma j’ Amona wa,
A o si ma ba O lo.
(Visited 1,070 times, 1 visits today)