1. AJIGBESE anu ni mi,
Mo ti ba majemu mi je;
Laifoya ninu pipe Re,
Mo gb’ ara at ore mi wa.
2. Eru ofin at’ Olorun
Ko ri ipa sa lodo mi;
Igboran Olugbala mi
Bo gbogbo ese mi mo ‘le.
3. Ise ti ore Re bere
Ni agbara Re yio pari;
Amin, beni ileri Re,
A ko si gbo p’ o saki ri.
4. Ko s’ ohun kan l’ aiye, l’ orun,
T’ isiyi, ab’ eyi ti mbo,
T’ o le mu ki ife Re ye,
Tabi k’ o ja mi l’ owo Re.
5. Oruko mi lo ko le pare
Kuro li atewo Re lai!
O wa li okan aiya Re,
Ore-ofe l’ o ko sibe.
6. Daju, emi yio wa titi,
A ti san owo ‘lele mi;
Awon t’ orun le ta mi yo
L’ ayo sugbon ki se l’ ebun.
(Visited 535 times, 1 visits today)