1. OKAN mi yin Oba orun,
Mu ore wa sodo Re;
‘Wo t’ a wo san, t’ a dariji,
Tal’ a ba ha yin bi Re?
Yin Oluwa,
Yin Oba ainipekun.
2. Yin, fun anu t’ O ti fihan,
F’ awon baba n’nu ponju;
Yin, i, okan na ni titi,
O lora lati binu,
Yin Oluwa,
Ologo n’nu otito.
3. Bi baba ni O ntoju wa,
O si mo ailera wa;
Jeje l’ O ngbe wa l’ apa Re,
O gba wa lowo ota,
Yin Oluwa,
Anu Re yi aiye ka.
4. A ngba b’ itanna eweko,
T’ afefe nfe, t’ o si nro
‘Gbati a nwa, ti a si nku,
Olorun wa bakanna;
Yin Oluwa,
Oba alainipekun.
5. Angel’, e jumo ba wa bo,
Enyin nri lojukoju;
Orun, osupa, e wole,
Ati gbogbo agbaiye,
E ba wa yin
Olorun Olotito.
(Visited 24,710 times, 21 visits today)