1. YIN Olorun Abra’am,
T’ o gunwa lok’ orun,
Eni agba aiyeraiye,
Olorun ife;
Emi Jehofa Nla,
T’ aiye t’ orun njewo;
Mo yin oruko mimo Re,
S’ apata mi.
2. Yin Olorun Abra’am,
Nipa ase Eni
Ti mo dide mo nwa ayo
Low’ otun Re;
Mo ko aiye sile,
Ogbon at’ ogo re:
Mo fi On nikansoso
Se odi mi.
3. O f’ ara Re bura,
Mo gbekel’ oro Re;
Ngo f’ apa iye idi fo
Lo sok’ orun;
Emi y’o w’ oju Re,
Ngo bo ife ‘jinle
Ngo korin ‘yanu ore Re
Titi aiye.
4. B’ ipa ara baje,
T’ aiye t’ Esu dena,
Ngo dojuko ile Kenaan
Nip’ ase Re;
Ngo la ibu koja,
Ngo tejumo Jesu;
Larin aginju t’ o l’ eru
Ngo ma rin lo.
5. S’Olorun Oba l’oke,
L’olor’Angeli nke
Wipe, Mimo, Mimo, Mimo
Olodumare;
Eniti o ti wa,
Ti y’o si wa lailai,
Emi, Jehofa Baba nla,
Kabiyesi.
6. Gbogb’ogun Asegun,
Yin Olorun l’oke
Pe kab’yesi, Baba, Omo,
Emi Mimo,
Olorun Abraham,
Olorun mi pelu,
K’Ola at’iyin ailopin
K’o je tire. Amin.