1. FUN aanu t’ o po b’ iyanrin,
Ti mo ngba lojojo
Lat’ odo Jesu Oluwa,
Kili emi le tun?
2. Kili ohun ti mo le fun un
Lat’ inu okan mi?
Ese ti ba gbogbo re je,
Ofo li o si je.
3. Eyi l’ ohun t’ emi o se,
F’ ohun t’ O se fun mi;
Em’ o mu ago igbala,
Ngo kepe Olorun.
4. Eyi l’ope ti mo le da,
Emi osi, are;
Ngo f’ ebun Re se iyanju
Lati ma bere si.
5. Emi ko le sin b’ o ti to,
Nko n’ ise kan t’ o pe;
Sibe ngo du ki nsogo pe
Gbese mi l’ o po ju.
(Visited 6,799 times, 24 visits today)