1. ITE anu! E je k’a lo
Lati gba adura;
Olorun ‘fe y’o sanu fun
Awon t’o nsin nibe.
2. Ite anu! A, n’ite ns
L’ekun wa ti nkunle;
Olorun si nro ‘jo ‘bukun
Nigbakugba t’a lo.
3. ‘Te anu! Enyin mimo ye,
Ite na si sile;
Fi edun nyin han Olorun,
Si wa ‘di ife Re.
4. A ko le sai fe ‘te anu,
Niwon bi a ti wa,
Ati onigbowo, titi
Iku y’o pa wad a.
5. ‘Gbana oju Jesu yio tan
‘Mole y’ite na ka,
A ki o si mo aini mo,
A k’y’o wa ‘te anu.
(Visited 729 times, 1 visits today)