YBH 305

NINU gbogbo iji ti nja

1. NINU gbogbo iji ti nja,
Ninu gbogbo igbi ‘ponju,
Abo kan mbe ti o daju,
O wa labe ite-anu

2. Ibi kan wa ti Jesu nda
Ororo ayo s’ ori wa;
O dun ju ibi gbogbo lo,
Ite-anu t’a f’ eje won.

3. Ibi kan wa fun idapo,
Nibi ore npade ore;
Lairi ‘ra, nipa igbagbo
Nwon y’ ite-anu kanna ka.

4. A! b’ idi l’ a o fo sibe,
O dabi aiye ko si mo,
Orun wa ‘pade okan wa,
Ogo sib o ite-anu.

(Visited 2,140 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you