YBH 332

OLUWA, ki s’agbara mi

1. OLUWA, ki s’agbara mi
Bi mo ye, bi mo ku;
Lati sin O ni ipin mi,
Iwo ni si fun ni.

2. B’emi mi gun emi o yo
Lati sin O titi,
B’ o si kuru, em’ o se ko
Lati lo ‘le orun?

3. Ona mi ko s’okun ju ‘yi
Ti Jesu pa ti rin;
Ko s’eniti wo ‘joba Re
Lai gb’ona t’ O la ‘le.

4. Wa, Oluwa, gbat’or’-ofe
Mu mi ri oju Re;
B’ise Re l’aiye ba l’adun,
B’ogo Re o ti ri?

5. ‘Gbana l’arodun mi y’o pin,
Are at’ese mi;
Ngo sidapo m’awon mimo,
Ti nyin oruko Re.

6. Emi ko mo b’orun ti ri
Oju gbagbo sokun;
Sugbon Jesu mo, eyi to,
Ngo si wa pelu Re.

(Visited 603 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you