1. ONA Re, Oluwa,
B’ o ti wu k’ o su to,
Masai f’ owo ‘tun Re to mi,
Yan ipa mi fun mi.
2. Nko gbodo yan ‘pin mi,
Nko tile je yan a;
Sugbon yan fun mi, Olorun,
Ngo si ma rin dede.
3. Kun ago mi pelu
Ayo tabi edun,
B’ o ba ti ye l’ oju Re sa,
Ki O yan ipin mi.
4. Yan ore mi fun mi,
Aisan tab’ ilera,
Yan ayo at, aniyan mi,
Aini tabi oro.
5. Yiyan ki se t’emi
Ninu ohun gbogbo;
Se agbara at’ oluto,
Ogbon, on gbogbo mi.
(Visited 963 times, 1 visits today)