1. MA toju, Jehofah nla,
Ero l’ aiye osi yi,
Emi ko l’ okun, iwo ni,
F’ ow’ agbara di mi mu,
Onje orun,
Ma bo mi titi lailai.
2. S’ ilekun isun ogo ni,
Orisun imarale;
Jeki imole Re orun
Se amona mi jale;
Olugbala,
S’ agbara at’ asa mi
3. Gba mo ba te eba Jordan’
Da ajo eru mi nu,
Iwo t’ O ti segun iku,
Mu mi gunle Kenaan je;
Orin iyin
L’ emi o fun O titi.
(Visited 10,038 times, 14 visits today)