YBH 336

BABA mi, ‘gba mo nsako lo

1. BABA mi, ‘gba mo nsako lo,
Kuro l’ ona Re l’ aiye yi;
Ko mi kin le bayi pe,
Se ‘fe Tire.

2. B’ ipin mi l’ aiye ba buru,
Ko mi ki ngba, ki nmase kun!
Ki ngbadua t’ o ko mi, wipe,
Se ‘fe Tire.

3. B’ o ku emi nikansoso,
Ti ara on ore ko si;
N’ iteriba ngo ma wipe,
Se ‘fe Tire.

4. B’ O fe gba ohun owo mi,
Ohun t’ o se owon fun mi,
Ngo fi fun O, se Tire ni?
Se ‘fe Tire.

5. Sa fi Emi Re tu mi ninu,
Ki On k’ o si ma ba mi gbe;
Eyit’ o ku, o d’ owo Re,
Se ‘fe Tire.

6. Tun ‘fe mi se l’ ojojumo,
K’ o si mu ohun na kuro,
Ti ko je k’ emi le wipe,
Se ‘fe Tire.

7. Nje ‘gbat t’ emi mi pin l’ aiye,
N’ilu t’ o dara ju aiye,
L’ emi o ma ko’rin titi,
Se ‘fe Tire.

(Visited 1,196 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you