YBH 337

MO ti se ‘leri, Jesu

1. MO ti se ‘leri, Jesu,
Lati sin O d’ opin;
Ma wa lodo mi titi,
Baba mi, Ore mi,
Emi k’ y’o beru ogun,
B’ Iwo ba sunmo mi,
Emi ki y’o si sina,
B’ O ba f’ ona han mi.

2. Je kin mo p’ O sunmo mi,
‘Tor’ ibaje aiye;
Aiye fe gba okan mi,
Aiye fe tan mi je,
Ota yi mi kakiri,
L’ ode ati ninu;
Sugbon Jesu sunmo mi,
Dabobo okan mi.

3. Je ki emi k’ o ma gbo,
Ohun Re, Jesu mi,
Ninu igbi aiye yi,
Titi nigbagbogbo,
So k’ o f’ okan mi bale,
Te ‘ri okan mi ba;
So k’ emi le gbo Tire,
‘Wo Olutoju mi.

4. ‘Wo ti se ‘leri Jesu
F’ awon t’ o tele O,
Pe ibikibi t’ O wa,
L’ awon yio si wa;
Mo ti se ‘leri Jesu,
Lati sin O d’ opin,
Je kin ma to O lehin,
Baba mi, O re mi.

5. Je kin ma ri ‘pase Re
Ki nle ma tele O:
Agbara Re nikan ni,
Ti mba le tele O,
To mi, pe mi, si fa mi,
Di mi mu de opin
Si gba mi si odo Re,
Baba mi, Ore mi.

(Visited 1,993 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you